NNPCL tun ti ja owo bẹntiroolu walẹ kaakiri Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 25, 2024

NNPCL tun ti ja owo bẹntiroolu walẹ kaakiri Naijiria


Ileeṣẹ Nigerian National Petroleum Company Limited, NNPCL, tun ti ja owo jaala epo bẹntiroolu silẹ kaakiri Naijiria.

N965 naira ni ileeṣẹ NNPCL ja owo jaala epo naa si niluu Abuja, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

L'awọn ipinlẹ miran bii Eko, ₦925 naira ni NNPCL n ta jaala epo bẹntiroolu, nigba ti wọn n ta jaala epo ni ₦950 nipinlẹ Ogun.

₦1040 ni ileeṣẹ NNPCL n ta epo bẹntiroolu kaakiri Naijiria tẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, ayipada ti wa.

Bakan naa, awọn ileepo miran bii MRS ti bẹrẹ sii ta jaala epo bẹntiroolu ni ₦935 kaakiri Naijiria.

Ṣaaju asiko yii, ileeṣẹ Dangote PLC lo ti kọkọ ja owo jaala epo wọn silẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni ileepo.

N899 ni Dsngote ja owo jaala epo wọn si lati N1020.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI