Bo tilẹ jẹ pe ko jẹ iyalẹnu fawọn kan lori bi olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ ko ṣe yọju sibi eto aba eto iṣuna ti Gomina Dapọ Abiọdun gbe lọ siwaju ile igbimọ aṣofin, sibẹ ọrọ naa ṣi n kọ awọn eeyan lominu.
Loni, Ọjọru tii ṣe Wẹside, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila ni Gomina Abiọdun gbe aba eto iṣuna lọ siwaju ile igbimọ aṣofin lati ṣagbeyẹwo rẹ ko to di pe wọn buwọ lu.
Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ nidi oṣelu ati lẹnu iṣẹ ijọba, to fi mọ awọn ọba alaye ni wọn wa nibi eto ọhun, ti ile igbimọ naa si kun fọnfọn.
Bo tilẹ jẹ pe ki eto ọhun too bẹrẹ lawọn kan ti n sọ pe o ṣee ṣe ki Ọnarebu Oluọmọ ma yọju sibẹ, sibẹ awọn kan n sọ pe ọkunrin naa to n ṣoju agbegbe Ifọ sọ pe ọkunrin naa yoo pa itiju ti, yoo si yọju.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 ti a wa yii ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa rọ Ọnarebu Oluọmọ nipo rẹ, lori ẹsun aṣemaṣe ati aṣilo ipo pẹlu agbara.
Awọn ọmọ ile igbimọ naa marundinlọgbọn ninu mẹrindinlọgbọn ni wọn buwọ lu iwe ti wọn fi yọ Oluọmọ nipo.
Latigba naa la gbọ pe Oluọmọ ko ti yọju sohun ti wọn n ṣe nile igbimọ naa mọ, koda ti wọn ni kii yọju sawọn akanṣe eto tijọba ipinlẹ Ogun n gbe kalẹ.
Bi Ọnarebu Oluọmọ ko ṣe yọju sile igbimọ aṣofin to, sibẹ, iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe ọkunrin naa ṣi n gba awọn ẹtọ rẹ gẹgẹ bi aṣofin.
Ẹnikan to sunmọ ile igbimọ aṣofin naa ti a fi orukọ bo laṣiri jẹ ko ye wa pe nitori itiju bi wọn ṣe yọ ọkunrin naa nipo lo fa a ti ko fi yọju.
Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii ni Ọnarebu Oluọmọ ko tii sọ idi pataki to fi sa nibi aba eto iṣuna naa, ṣugbọn ti a fi n da a yin loju pe bi ọkunrin naa ba sọrọ jade, a maa mu iroyin naa wa fun un yin.
No comments:
Post a Comment