Titi di asiko ti a fi pari akojọpọ iroyin yii ni awọn mọlẹbi ọdọmọdekunrin ti ẹ n wo aworan rẹ yii ṣi n wa a.
Wọn ni ọjọ Aje, ọsẹ ti a wa yii, ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni ọmọdekunrin naa, Abd Quadri jade nile, to si dagbere wi pe oun fẹẹ lọ kirun ni mọṣalaṣi to wa nitosi ile wọn.
Adugbo Oko-Filling to wa ni Tipper Garage, Akute nipinlẹ Ogun ni Quadri n gbe pẹlu awọn obi rẹ.
Latigba to si ti lọ mọṣalaṣi ni ko ti pada sile mọ.
Gbogbo igbiyanju lati ri Quadri lo ja si pabo, eyi lo je ki wọn lọ fi to awọn ọlọpaa leti.
Fun ẹnikẹni to ba kofiri Quadri nibikibi, ẹ le fi to awọn ọlọpaa leti tabi ki ẹ pe eyikeyi ninu awọn ẹrọ ibanisọrọ yii, 08101749883, 07032055469 tabi 08036800005
No comments:
Post a Comment