Mo ṣẹṣẹ bẹrẹ aye jijẹ ni - Iya Rainbow sọrọ lẹni ọdun mejilelọgọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 9, 2024

Mo ṣẹṣẹ bẹrẹ aye jijẹ ni - Iya Rainbow sọrọ lẹni ọdun mejilelọgọrin


Gbajugbaja agba oṣerebinrin nni, Wolii Idowu Philips ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mama Rainbow ti sọ pe ọdun mejilelọgọrin toun pe yii, oun ṣẹṣẹ bẹrẹ igbe aye tuntun ni.
 
Agba oṣere naa lo sọrọ yii ninu ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara ti Instagram rẹ laipẹ.
 
Mama naa to yan iṣẹ Wolii laayo papọ mọ iṣẹ tiata sọ pe gbogbo igba loun maa n dabi ọmọ ọdun marundinlaadọta, nitori pe ọlọkan ọmọde loun jẹ.
 
O ni oun ko tii dagba, ati pe ọjọ ori ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu aye jijẹ, toun si loun yoo gbadun ara oun dọba.

“Onka lasan ni ọjọ ori jẹ! 🎉 Ni ọdun mejilelọgọrin, mo ti pinnu wi pe igbe aye ṣẹṣẹ n bẹrẹ ni. Mo kọ lati darugbo—ojoojumọ ni mo maa n dabi ọmọ ọdun marundinlaadọta! 💪✨ Duro digbi ninu ọkan, awọn ọrẹ mi. #YoungAtHeart #82IsTheNew45 #NeverTooLate #AgelessVibes” 😄😄😄❤️❤️”



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI