Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ eto lati fun awọn ohun ọsin kaakiri ipinlẹ naa labẹrẹ ajẹsara, lati dena ajakalẹ arun ti wọn pe ni anthrax to ṣeeṣe ko wọle.
Awọnb ẹkun ipinlẹ naa bii Ariwa ati Aarin Gbungbun ni eto ọhun ti fẹẹ bẹrẹ nigba ti wọn n ṣe ifilọlẹ naa laipẹ yii.
Ninu atẹjade ti Yusuf Ganiyu Adebisi to jẹ agbẹnusọ Kwara L-PRES fi sita, o ni eto ọhun bẹrẹ lakọtun lẹyin ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ifilọlẹ niluu Lamba, ijọba ibilẹ Asa laipẹ yii.
O ni awọn igbimọ ti yoo ṣagbatẹru eto ọhun ni wọn jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa itọju ohun ọsin lati awọn ileeṣẹ bii Ministry of Agriculture, Animal Health Technologists, Private Veterinary Doctors, Bureau of Statistics; to fi mọ awọn ileeṣẹ eleto aabo bii Directorate of State Security (DSS), Nigeria Security And Civil Defence Corps (NSCDC).
Awọn wọnyi lo wa nibi eto naa ti Dokita Bukola Richard to jẹ alakoso ajọ Livestock Productivity and Resilience Support Project (L-PRES) lewaju fun nijọba ibilẹ Baruten.
Emir tiluu Okuta, Ọmọwe Abubakar Sero Idris ko gbẹyin nibi ifilọlẹ ọhun.
Nibẹ ni wọn ti sọ pe abẹrẹ ajẹsara anthrax naa yoo tun dena awọn ohun ọsin lati ko arun ti wọn n pe ni "zoonotic".
No comments:
Post a Comment