Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Deeper Christian Life Ministry, Pasistọ Williams Kumuyi ti sọ pe dandan ni ki awọn ẹlẹsin Kristẹẹni bẹrẹ sii kopa ninu eto oṣelu orileede, paapaa ni Naijiria.
Pasitọ Kumuyi lo sọ eyi nibi apejọ awọn akọroyin ti wọn ṣe lati fi bẹrẹ isọji ita gbangba to fẹẹ bẹrẹ ni ẹka olu-iya ijọ naa to wa nipinlẹ Ogun laipẹ yii.
Alakoso agba naa jẹ ko di mimọ pe “Bi awọn Kristiẹni ko ba kopa ninu eto oṣelu, o tunmọ si pe awọn ẹya yii lai si Kristiẹni nibẹ nikan ni yoo maa dari wa sibi to yẹ ka lọ, ti wọn yoo si sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si orileede.
“Atipe awọn Kristiẹni ko lẹtọọ lati ṣaniyan bi wọn ko ba fi ara wọn silẹ lati mu ohun gbogbo padabọ sipo.
“Gbogbo wa la ri awọn nnkan to n ṣẹlẹ. Awọn adari wa ni wọn dibo yan, boya a n sọrọ nipa ijọba ibilẹ, ijọba ipinlẹ ati apapọ, tabi ijọba orileede.”
No comments:
Post a Comment