Ko sohun meji ti Sheik Bello duro fun, to kọja otitọ - Oluwoo tilu Iwo sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 6, 2024

Ko sohun meji ti Sheik Bello duro fun, to kọja otitọ - Oluwoo tilu Iwo sọrọ


Oluwo tilu Iwo, Ọba AbdulRosheed Adewale Akanbi ti ṣapejuwe agba olori ẹsin nni, Sheik Muhydeen Ajani Bello gẹgẹ bi olotitọ to duro ṣinṣin.

Kabiyesi naa lo sọrọ yii ninu atẹjade ibanikẹdun to fi sita lati fi kẹdun iku agba oni waasi ọhun to jade laye loni, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun 2024.

Ọba alaye ilẹ Iwo jakejado naa sọ pe adanu nla ni iku Sheik Bello jẹ fun agboole Musulumi kaakiri agbaye.

Telu kinni jẹ ko di mimọ pe aaye ti oloogbe naa ṣi silẹ yoo ṣoro lati ri ẹni to le dii pa.

“Sheik Muhydeen jẹ aṣaaju ati olufọkansin ninu ẹsin Islam, ẹni to n fi otitọ ṣe waasi, to si duro lori otitọ naa titi to fi jade laye.

“O duro gẹgẹ bii otitọ, to si n sọ otitọ naa lai wo iru ẹni ti yoo ta ba. Ko si iru eeyan bii tirẹ to tun le maa waasu bo ṣe n ṣe e.

“O gbe igbe aye to pe ye. Asiko yii kii ṣe asiko fawọn mọlẹbi rẹ lati kẹdun. Mo rọ awọn iyawo ati awọn ọmọ lati maa dupẹ fun igbe aye to gbe. Ilana rere to ṣee jowu lo fi silẹ lọ.”

Bi Oluwo ṣe gbadura pe ki Allah forijin oloogbe naa, lo tun gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI