Aarẹ Galatasaray, Dursun Özbek ti sọ pe ko sẹni to le fipa le gbajugbaja agbabọọlu ọwọ iwaju nni, Victor Osimhen kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu loṣu Kinni, ọdun 2025.
Özbek sọ pe Osimhen yoo ṣi wa pẹlu awọn titi digba ti yoo fi polongo lati kuro nibẹ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan, ọdun yii ni wọn fipa le Osimhen kuro ninu ẹgbẹ Napoli ti idije Serie A lọ si Galatasaray.
Kọlọfin kan to wa ninu iwe adehun ti fi tare ọmọ Naijiria naa kuro ni Napoli ni pe ọkunrin naa le lọ si ẹgbẹ agbabọọlu to ba wu ninu oṣu Kinni, ọdun to n bọ.
Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita wi pe Osimhen n gbaradi lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United.
Ṣugbọn Özbek ninu ọrọ rẹ, jẹ ko di mimọ pe kọlọfin kan to ṣoro diẹ wa fun Osimhen lati kuro ni aarin meji saa.
“Agbabọọlu wa ni fun saa yii. Kọlọfin kan wa fun un lati kuro ni aarin meji saa yii. Gẹgẹ bi adehun wa, o maa gba bọọlu fun wa titi di ipari saa yii,” o sọ fun A Spor.
“Ki ẹnikẹni ma ṣe ṣii lọkan. O maa ṣe ipinnu funra rẹ ni ipari saa yii. To ba fẹẹ tẹsiwaju pẹlu Galatasaray, o le tẹsiwaju.”
No comments:
Post a Comment