Kii ṣe gbogbo adari ni Ọlọrun lọwọ si, eṣu naa ni agbara lati yan adari tiẹ - Ọbasanjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 9, 2024

Kii ṣe gbogbo adari ni Ọlọrun lọwọ si, eṣu naa ni agbara lati yan adari tiẹ - Ọbasanjọ


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe dandan ni ki adari ti eṣu ba yan kuna, ati pe adari ti Ọlọrun ba yan nikan lo ṣe aṣeyọri.

 
Ọbasanjọ ni bi Ọlọrun ṣe ni agbara, naa ni eṣu lagbara lati fi adari si ipo, ṣugbọn ti ko ni igbala.
 
Balogun Owu tun fi kun ọrọ rẹ pe oun ko ba wọn nigbagbọ ninu ọrọ ti wọn maa n sọ wi pe gbogbo adari ni Ọlọrun, to si lọwọ si.
 
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọrọ yii jade lalẹ ọjọ Aiku to kọja, lori eto ti wọn pe ni “Boiling Point Arena.”

Ifọrọwerọ naa ti ileeṣẹ redio aladani kan niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun gbe safẹfẹ, ni wọn fi ṣagbeyẹwo iṣakoso Ọbasanjọ si ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko yii.

Baba naa ni;

“Ọpọ awọn adari lo jẹ pe Ọlọrun lo n palẹ wọn mọ, to si n fi wọn sipo, nigba ti iru eyi ba si n ṣẹlẹ, gbogbo anfaani tabi ohun ti wọn ba dawọ le lo maa n yọri si rere, ju ko yẹ pe eeyan lo sọ ara rẹ di olori, leyi ti ko lọwọ Ọlọrun ninu.
 
“Ati pe awọn eeyan maa n sọ pe gbogbo adari ni Ọlọrun yan, emi ko gba ọrọ naa gbọ. Eṣu naa le yan adari. Bi a ba ọrọ Job ṣe apẹẹrẹ, a maa rii pe eṣu n lọ kaakiri, ko to di pe o lọ ba Ọlọrun, Ọlọrun si pọn Job le niwaju eṣu, ṣugbọn ti eṣu sọ pe nitori awọn nnkan ti Job n ri gba lọwọ Ọlọrun lo fi duro ṣinṣin.
 
“A ni lati gba wi pe eṣu wa, to si tun ni agbara, ko ni igbala, ṣugbọn to ni agbara, ati pe a ko le fi oju tẹmbẹlu agbara eṣu,” Ọbasanjọ sọrọ.
 
Siwaju sii ni Ẹbọra Owu sọ pe  o ṣe pataki lati gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, ati pe igbesẹ yii gbọdọ bẹrẹ lati ọdọ awọna dari ati alakoso, ko to di pe wọn ṣe aṣeyọri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI