Iya arugbo wọ gau, oogun oloro 'Codeine' to gbe lo ṣakoba fun un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 9, 2024

Iya arugbo wọ gau, oogun oloro 'Codeine' to gbe lo ṣakoba fun un


Ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro lorileede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ iya agbalagba kan, 
Ramata Bola Adeyemo lori ẹsun gbigbe egboogi oloro.
 
Ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja yii, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun yii ni ọwọ tẹ mama agbalagba, ẹni ọdun mejilelọgọta naa lojule kejilelọgọtam adugbo Ọdunfa, Lagos Island.
 
Lita to din diẹ ni mọkanlelogun (20.6 litres) la gbọ pe wọn ka mọ ọn lọwọ lasiko tọwọ palaba rẹ segi.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe ọwọ ti tẹ gbajumọ Alaaji kan ladugbo Ogundana, to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko.
 
Alaaji ọhun, Lawan Manga ni wọn mu l'Ọjọbọ, ọsẹ to kọja pẹlu kilogiraamu 4.7kgs igbo 'Indian Hemp', ati kilogiramu tramadọ 1.3kgs.
 
Bakan naa ni ajọ NDLEA tun jẹ ko di mimọ pe egboogi oloro tramadọ to le ni ẹẹdẹgbẹta (511,000) ni wọn ti gba lagbegbe Hildi, opopona Askira Uba, ipinlẹ Adamawa.
 
NDLEA sọ pe aarọ kutu ọjọ Fraide naa lawọn gba awọn egboogi oloro ọhun ninu mọto Toyota Sienna.
 
Wọon jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to wa ninu mọto Sienna ọhun ni wọn na papa bora ni kete ti won kofiri awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA laisko ti wọn n ṣiṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI