Bi eeyan ba fi ara jin fun iṣẹ, o di dandan ki gbogbo agbaye rii, ki wọn si gbe oṣuba kare fun iru ẹni bẹẹ. Eyi lo fa bi ipinlẹ Kwara ṣe gba aami ẹyẹ ipo lẹka eto ilera alabọde lẹkun aarin gbungbun Ariwa ilẹ Naijiria.
Igba keji ree ti ipinlẹ Kwara yoo maa gba aami ẹyẹ yii lera wọn, ipinlẹ naa lo ṣe ipo kinni lọdun to kọja fun ọdun 2022/2023, ti wọn si tun ti gba ti ọdun 2023/2024 bayii.
Wọn ni ipinlẹ Kwara lo n ṣe daadaa julọ ninu awọn ipinlẹ to wa lẹkun aarin gbungbun Ariwa (North Central) nibi idije eto ilera alabọde ti a mọ si ‘2023/2024 Primary Health Care Leadership Challenge'.
Kii ṣe pe ipinlẹ Kwara gbegba oroke nikan, wọn tun jẹ ẹbun owo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta owo dọla ($500,000) ti wọn yoo na lati ra awọn irinṣẹ ni ibamu pelu agbekalẹ ajọ UNICEF ati ẹgbẹ awọn gomina Naijiria.
Awikonko gbọ pe kii ṣe iṣẹ kekere ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n ṣe lẹka eto ilera alabọde, koda ti wọn ni lara ohun ti gomina mu lọkunkundun ni lati jẹ ki araalu jẹ igbadun mudunmudun eto ilera alabọde.
Agbekalẹ eto naa ni lati fun awọn ijoba ni koriya lati le maa ṣiṣẹ siwaju sii nipa mi mu idagbasoke ba eto ilera.
Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Kwara, Dokita Amina Ahmed el-Imam ati akọwe ajọ to n ri sọrọ idagbasoke eto ilera alabọde nipinlẹ Kwara, Dokita Nusirat Elelu ti wọn ṣoju ijọba jẹ ko di mimọ pe iwuri nla ni aami ẹyẹ ọhun jẹ.
Gbọngan ayẹyẹ Banquet to wa ni State House niluu Abuja ni eto ọhun ti waye, nibi ti igbakeji Aarẹ, Kashim Shetimma; awọn gomina Naijiria ti alaga wọn, Abdulrahman Abdulrazaq lewaju; Minisita feto ilera ni Naijiria, Ọjọgbọn Muhammed Ali Pate arawọn miran ti peju.
No comments:
Post a Comment