Awaye ma lọ kan ko si, ọrun dẹdẹ mai tii kanju, gbogbo la ṣi n bọ. Bi ọdun 2024 ṣe n kasẹ nilẹ, ti a n ṣe ipalẹmọ lati wọnu ọdun tuntun, orin ọpẹ lo yẹ ki awa ti a wa laye mu sẹnu fun oore ọfẹ nla ti a ri gba.
A fẹẹ boju wẹyin lati wo diẹ lara awọn gbajugbaja oṣere tiata ati amuludun ti wọn ba ọdun 2024 wọlẹ.
Oloye Adedeji Aderemi - Ọlọfa Ina
Ọkan pataki lara awọn agba oṣere ti wọn sọ iṣẹ tiata di irọrun ni Oloogbe, Oloye Adedeji Aderemi ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye mọ si Ọlọfa Ina. Ọpọ ọdun ni Ọlọfa Ina fi wa nidi iṣẹ tiata, koda, iṣẹ naa lo ṣe titi ti ọlọjọ fi de.
Ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024 ni iroyin iku agba oṣere naa jade sita, nigba ti alakoso eto Best of Nollywood (BON), Seun Oloketuyi; Saidi Balogun ati miran kede lori ikanni Instagram.
Baba naa jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrin.
Jimi Solanke - Baba Agba
Ọrọ iku Ọlọfa Ina lo ṣi n ja nilẹ nigba ti iroyin iku agba ọjẹ nidi iṣẹ orin nni, Alagba Jimi Solanke naa tun gba igboro lọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun 2024.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọrin ni ọmọ bibi ilu Ipara Remo naa wa ko to di pe ọlọjọ de. Bi wọn ba n sọ nipa awọn to sọ iṣẹ orin di irọrun, ọkan gboogi ni Oloogbe Jimi Solanke jẹ.
Yatọ si pe oloogbe naa jẹ agba onkọrin, bẹẹ lo tun jẹ agba ọjẹ nidi iṣẹ tiata, to tun n kewi, onsọtan ati alakoso ere, to fi mọ Ọmọwe ati bẹẹbẹẹlọ ni Solanke.
Aisan rampẹ lo ṣe baba naa, ti wọn fi sare gbe e lọ si ile iwosan awọn olukọni ti Babcock, nibi to ti pada ki aye pe o digboṣe.
Ethel Ekpe
Aisan jẹjẹrẹ lo pa ilu mọ-ọn-ka oṣerebinrin Igbo ati Oyinbo nni, Ethel Ekpe. Ko sẹni to le gbagbe ipa to ko ninu ere agbelewo Basi and Company, gẹgẹ bii ‘Segi’.
Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni oserebirin ti aye n gba tiẹ nigba naa wa lasiko to jade laye.
Ọjọ kẹta ti Jimi Solanke jade laye ni iroyin iku Ekpe naa jade lọjọ keje, oṣu Keji, ọdun 2024.
Tolani Quadri Oyebamiji - Sisi Quadri
'Irọ ni, bẹẹni-bẹẹkọ, ko le jẹ bẹẹ', wọnyi lọrọ kayeefi to n jade lẹnu awọn ololufẹ ere tiata lorileede Naijiria nigba ti iroyin iku Tolani Quadri Oyebamiji ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye mọ si Sisi Quadri jade sita.
Ọmọ bibi ilu Iwo nipinlẹ Osun naa lo jade laye lọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 2024, lẹyin aisan rampẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Asiko ti ogo Sisi Quadri, oṣere apanilẹrin naa tun n buyọ yatọ nidi ere oniṣẹju perete lori ayelujara (skit-making) ni iku wọle mu-un lọ lẹni ọdun mẹrinlelogoji, to si ba ọpọ eeyan lọkan jẹ gidi.
Inu sinima agbelewo igba naa, Ṣẹranko Ṣeniyan to jade lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2004 ni ogo rẹ kọkọ buyọ, to si jẹ pe ogun ọdun lẹyin rẹ lo fi ilẹ ṣe aṣọbora.
John Okafor - Mr Ibu
Iru kileyi lawọn eeyan n sọ nigba ti iroyin tun jade sita wi pe gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu nni, John Okafor, ti awọn eeyan mọ si Mr Ibu naa ku.
Ọjọ keji ti Sisi Quadri jade laye, naa ni Mr Ibu doloogbe, iyẹn lọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun 2024, to si fẹẹ dabi ẹni pe niṣe lawọn mejeeji ṣe ipade lati pade lọrun.
Ile iwosan ti wọn pe ni Evercare to wa niluu Lekki, ipinlẹ Eko ni Mr Ibu dakẹ si lẹni ọdun mejilelọgọta lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ abẹ.
Amaechi Muonagor
Adẹrinpoṣonu naa ni gbajugbaja oṣere tiata nni, Amaechi Muonagor, ẹni to jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Aisan kidinrin ni baba naa ba fa a, ko to di pe o pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024.
Ọpọ ipa to jọju, to tun jẹ manigbagbe lo ko lagboole tiata nigba aye rẹ, ko to di pe ọlọjọ de.
Aderounmu Aderonke - Esther
Ko sohun meji to n jẹ ki ọrọ iku Adejumoke Aderounmu, ti ọpọ mọ ninu sinima Jenifa’s Diary gẹgẹ bi Esther maa ya ọpọ eeyan, bi ko ṣe pe ko ṣaisan to fi ku.
Wọn ni oju oorun ni Adejumoke gba sọda sọrun alakeji lọjọ to dagbere faye lẹni ogoji ọdun.
A gbọ pe ọmọ bibi ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun naa n gbaradi lati lọ siluu Oyinbo ni iku wọle tọ ọ, to si mu lọ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.
Junior Pope Odonwodo
Niṣe ni ariwo ibanuje tun sọ lagboole tiata lorileede Naijiria, paapaa ni ẹka ti oloyinbo nni, nigba ti iroyin tun jade pe gbajugbaja oṣere nni, Junior Pope Odonwodo ti ku.
Inu ijamba oko oju omi ni iroyin fi to wa leti pe Junior Pope gba d'ọrun alakeji lojo kẹwaa, oṣu Kẹrin, lẹni ọdun mọkandinlogoji.
Fiimu agbelewo The Other Side of Life ni won n ya lọwọ lasiko naa, to fi pade iku ojiji lọna.
Onyeka Onwenu
Iyalẹnu nla patapata ni iku agba onkọrin nni, Onyeka Onwenu jẹ fum awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye.
Onyeka Onwenu to ku lẹni odun mejilelaadọrin, ko ṣaisan rara, ode ariya to ti lọ kọrin lo ku si ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.
Dayo Adewunmi - Sule Suebebe
Asiko ti gbogbo ọmọ Naijiria n ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọ iṣejọba awa-ara-wa kaakiri agbaye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ni iroyin iku ogbontarigi oṣere tiata naa, Dayo Adewunmi jade sigboro aye.
Adewunmi ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Sule Suebebe lo jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọrin, lẹyin aisan to ba a finra fun bii ọdun meji.
Stella Ikwuegbu
Ọjọ kẹrin lẹyin iku Sule Suebebe ni iroyin iku agba oṣerebinrin nni, Stella Ikwuegbu naa tun jade sita lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa.
Aisan jẹjẹrẹ ti ẹsẹ, iyẹn Leg Cancer ni wọn lo pa oṣerebinrin naa lalẹ ọjọ Aiku.
Sharon Okpamen
Ko si nnkan meji to jẹ ki iku Sharon Okpamen je iyalẹnu ati kayeefi fawọn ololufẹ, paapaa mọlẹbi rẹ ni bo ṣe jẹ pe ko ju bi ọjọ meloo to bímọ keji ni ọlọjọ de.
Ọdun 2010 ni ọmọ bibi ipinlẹ Edo naa bẹrẹ iṣẹ tiata, nigba ti Ọgbẹni John Okafor ti a mọ si Mr Ibu fi sinu ere rẹ to pe ni Touch Not My Crown.
Ọjọ manigbagbe ni ọjọ ti Sharon, ẹni ọdun marundinlogoji naa ku.
Charles Olumo (Agbako)
Bo tilẹ jẹ pe iku Oloogbe Abdulsalam Sanyaolu, ti awọn eeyan tun n pe ni Charles Olumo tabi Agbako kii ṣe oku ọfọ, sibẹ ko sẹni to fẹ ki baba naa fi aye silẹ.
Ọkan lara awọn agba oṣere ti dagba daadaa ni Agbako, to si ko ipa to jọju nidi iṣẹ tiata ko to ku.
Ọdun mọkanlelọgọrun-un ni Charles Olumọ ko to dagbere faye lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa.
Moses Korede Are - Baba Gbenro
'Black Thursday' ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 jẹ lagboole tiata, paapaa ti ẹka awọn Kristiẹẹni jẹ nigba ti iroyin iku Alagba Moses Korede Are, ti awọn eeyan tun n pe ni Baba Gbenro jade sita .
Asiko ti agboole tiata Kristẹni n gbadun Baba Gbenro, iku wọle mu agba onkọtan, oludari ere ati oṣere naa lọ lẹni ọdun marundinlaadọrin.
Bi a ti n gba a ladura pe ki Ọlọrun tubọ maa tẹ wọn si afẹfẹ rere, bẹẹ naa la tun n gba a ladura pe ki Ọlọrun bu ororo itura si ọkan awọn mọlẹbi wọn.
No comments:
Post a Comment