Ile-ẹjọ ju Olori Naomi ati Oriyọmi Hamzat sọgba ẹwọn n’Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 24, 2024

Ile-ẹjọ ju Olori Naomi ati Oriyọmi Hamzat sọgba ẹwọn n’Ibadan


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo ti paṣẹ pe ki Olori tẹlẹ ni fun Ọọni Ile-Ifẹ, Naomi Silekunola Ogunseyi sọgba ẹwọn Agodi nipinlẹ naa.

Yatọ si Olori Naomi, ile-ẹjọ tun sọ pe ki alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo, Oriyomi Hamzat ati ọga ile-ẹkọ girama tawọn Musulumi, Abdullahi Fasai naa wa lọgba ẹwọon ọhun.

Aṣẹ yii ko ṣẹyin itẹra-ẹni-pa to waye lọsẹ to kọja yii nibi ti Olori Naomi ti ṣagbatẹru eto pinpin ounjẹ ọdun fawọn ọmọde niluu Ibadan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọde ti ko din ni marundinlọgbọn ni wọn padanu ẹmi wọn, ti awọn mẹfa miran si tun farapa yannayanna.

Onidajọ Olabisi Ogunkanmi lo paṣẹ naa, pẹlu bi wọn ṣe ko awọn afurasi naa wọ kootu pẹlu eto aabo to pọ.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ ni wọn fi kan awọn mẹtẹẹta naa, nigba ti agbefọba sọ pe ẹsun naa tako abala 324 ninu iwe ofin ọdaran tipinlẹ Oyo, tọdun 2000.

Agbefọba naa sọ pe awọn mẹtẹẹta yii ni wọn lọwọ ninu eto nla to gba ẹmi ọpọ eeyan, eyi to sọ ọpọ mọlẹbi sinu ẹkun.

Onidajọ naa sọ pe ki awọn mẹtẹẹta yii wa lọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi gba amọran lati ọdọ ajọ Director of Public Prosecutions.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI