Ijọba Ogun gbe iwe aṣẹ ’CofO’ ti Shimawa le ileeṣẹ Adron Homes lọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 12, 2024

Ijọba Ogun gbe iwe aṣẹ ’CofO’ ti Shimawa le ileeṣẹ Adron Homes lọwọ


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti gbe iwe aṣẹ 'emi ni mo ni ilẹ' ti awọn eeyan mọ si 'Certificate of Occupancy', fun ti awọn ilẹ to wa lagbegbe Shimawa, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode le alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing lọwọ.
 
Ninu iroyin ti Maureen Echefu to jẹ akọwe iroyin ileeṣẹ Adron Homes fi ranṣẹ sawọn akọroyin, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, o ni funra gomina lo gbe iwe aṣẹ naa fun ọga awọn.
 
Ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe ohun ti fontẹ lu awọn dukia ileeṣẹ Adron Homes ti Treasure Park and Gardens Phase 2 (City of David), ati Treasure Park and Gardens phase 3 (Capetown Estate).
 
Atẹjade ọhun sọ pe kii ṣe pe ijọpba ipinlẹ Ogun gbe iwe aṣẹ naa le wọn lọwọ nikan, bi ko ṣe pe wọn tun fontẹ lu igbagbọ ti wọn ni, ninu wọn lori awọn dukia ati ilẹ ti wọn n ta.
 
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe igbakeji ree ti ijọba ipinlẹ Ogun yoo maa gbe iwe aṣẹ 'CofO' le ileeṣẹ naa lọwọ.
 
O ni gomina ana, Sẹnetọ Ibikunle Amosun lo kọkọ gbe iwe aṣẹ naa fun wọn lori awọn dukia ti Treasure Park and Gardens Phase 1 (Genesis Estate), ati Treasure Park and Gardens (Glasshouse Estate).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI