Ijọba ipinlẹ Kwara ti jade sita lati sọrọ lori awuyewuye to n lọ nigboro lori bi awọn oṣiṣẹ ijọba kan ko ṣe tii ri owo oṣu ati ajẹmọnu wọn fun oṣu Kọkanla, ọdun 2024 gba titi di asiko yii.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna nipinlẹ naa gbe jade lọjọ Aje, ọsẹ yii ni wọn ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa idaduro owo oṣu awọn oṣiṣẹ kan.
Atẹjade ọhun ti Hajia Hauwa Nuru to jẹ Kọmiṣanna feto iṣuna buwọ lu jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn oṣiṣẹ ijọba ni Kwara ni wọn ti ri owo oṣu wọn fun oṣu Kọkanla gba, nigba ti awọn miran ko tii ri.
Hajia Nuru sọ pe awọn ti wọn ko tii pari eto iforukọsilẹ wọn fun nọmba apapọ tijọba ipinlẹ naa ti wọn pe ni Kwara State Resident Registration Agency (KWSRRA) ti ijọba ti kede rẹ ni wọn ko tii le ri owo wọn gba.
Wọn ni lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla ni ijọba kede sita pe awọn to ba ti pari eto iforukọsilẹ lati gba nọmba KWASRRA nikan ni yoo ri owo oṣu wọn gba, ati pe oṣu mẹfa gbako ni ijọba fi silẹ fawọn oṣiṣẹ lati gba nọmba naa.
Hajia Nuru ti wa gba gbogbo oṣiṣẹ patapata lamọran lati tete lọ ṣe iforukọsilẹ fun nọmba naa, ki wọn ba a le ri owo oṣu wọn ati ajẹmọnu wọn gba ni eyikeyi ileeṣẹ KWSRRA to ba sunmọ wọn.
No comments:
Post a Comment