Ijọba Kwara ṣi opopona Unity fawọn araalu lati ṣọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 22, 2024

Ijọba Kwara ṣi opopona Unity fawọn araalu lati ṣọdun


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede ṣiṣi opopona Unity ati afara Murtala Muhammed Unity fun lilo araalu lati fi jẹ igbadun ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna.

Opin ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni ijọba kede wi pe awọn ti ṣi opopona naa, lati mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ laarin ilu.

Kọmiṣanna feto iṣẹ ode ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Kwara, Onimọ-ẹrọ Abdulquawiy Olododo, lo ṣalaye lẹkunrẹrẹ nibi abẹwo to ṣe sibi akanṣe iṣẹ naa niluu Ilọrin.

Nigba to n ṣalaye, o ni ọkan oun balẹ wi pe iṣẹ naa yanju, bo tilẹ jẹ pe ko tii pari tan, sibẹ o ni awọn yoo ṣi ti afara ọhun pa titi digba ti iṣẹ yoo pari patapata.

O ni awọn opopona to yi afara ọhun ka ti ṣee gba fawọn awakọ

Nibẹ lo ti ṣe ikilọ fawọn ọlọja lati ma ṣe patẹ sẹgbẹ titi, paapaa awọn ibi ti wọn ya silẹ fawọn ẹlẹsẹ lati maa rin, pẹlu ikilọ pe ẹni tọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin.

Lara awọn to wa nibẹ ni akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye ati amugbalẹgbẹlẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ idagbasoke, Onimọ-ẹrọ Ladi Yusuf.













No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI