Lojuna lati le jẹ ki awọn araalu tẹsiwaju lati maa jẹ mudunmudun eto oṣelu awa-ara-wa, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ohun ti ja owo ọkọ walẹ fun irọrun araalu
Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni ijọba Kwara gba bọọsi akero ti ko din ni ogun ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta tohun naa ko din ni ogun, iyẹn awọn to n lo afẹfẹ gaasi.
Eyii ni wọn gba labẹ eto ijọba apapọ ti wọn pe ni Presidential Compressed Natural Gas Initiative (PCNGI), lojuna lati mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ laarin ilu.
Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe agbekalẹ naa jẹ eyi ti ijọba fẹẹ fi ṣe iranwọ fun araalu nipa owo jaala epo rọbii to lọ soke, to si ni agbekalẹ naa yoo ṣe iranlọwọ gidi.
Lara awọn to wa nibi ifilọlẹ eto ọhun ni igbakeji gomina Kayọde Alabi; olori ile igbimọ aṣofin, Ọnarebu; adajọ agba ni Kwara, Onidajọ Abiọdun Adebara; Grand Kadi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun Shari'ah, Onidajọ Abdullateef Kamaldeen.
Bakan naa ni gbogbo awọn alẹnulọrọ nidi oṣelu ati iṣẹ ijọba ko gbẹyin nibẹ, to fi mọ alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Kwara, Ọmọọba Sunday Fagbemi; igbakeji alaga eto P-CNG, Ọgbẹni Toyin Zubair; alaṣẹ ati oludasilẹ B One Mobility Limited, Ọgbẹni Atul Saraf.
Ninu ọrọ gomina, o ni asiko yii gan an ni araalu nilo ijọba fun iranwọ, paapaa lẹka eto igbokegbodo ọkọ, to si ni owo ti awọn eeyan fi n wọ ọkọ lojumọ pọ fun wọn.
No comments:
Post a Comment