Ijọba Kwara gbe idanilẹkọọ ọlọjọ meji kalẹ fawọn olukọ lori oogun lilo ati itọju ara-ẹni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 18, 2024

Ijọba Kwara gbe idanilẹkọọ ọlọjọ meji kalẹ fawọn olukọ lori oogun lilo ati itọju ara-ẹni


Lojuna lati jẹ ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ati akẹkọọ wa ni ilera pipe, ati lati dena iku ojiji laarin awọn oṣiṣẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe eto idanilẹkọọ ọlọjọ meji kalẹ fawọn olukọ ile ekọ girama nipinlẹ naa.

Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori gbigbogun ti aṣilo oogun ati itọju lo kede eyi ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, ọsẹ yii.

O ni idanilẹkọọ naa ni awọn olukọ ile ẹkọ girama to jẹ tijọba yoo ti mọ nipa bi wọn ṣe le maa tọju ara wọn loore-koore, ati lati dena wahla ṣiṣe lẹnu iṣẹ.

Idanilẹkọọ ọhun ni wọn pe ni Drug Prevention, Treatment and Care (DPTC).

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe awọn olukọ naa yoo kọ nipa bi wọn ṣe kọ awọn akẹkọọ nipa didẹkun oogun lilo lọna aitọ, lati le gba ọjọ ọla wọn silẹ, ki wọn si maa ṣe ipolongo agbegbe to yera fun oogun lilo.

Ojule kejila, adugbo Onikanga, GRA to wa niluu Ilọrin ni idanilẹkọọ ọhun yoo ti waye, bẹrẹ lati agogo mẹjọ owurọ si mẹrin irọlẹ, ọjọ mejeeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI