Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ohun ti ṣetan lati bẹrẹ sii san ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ, iyẹn owo oṣu tuntun tijọba apapọ Naijiria fọwọ si.
Alaga igbimọ iṣakoso fasiti ipinlẹ Kwara, KWASU to wa ni Malete, Ọjọgbọn Abdulganiyu Ambali, lo kede laipẹ yii, to si ni ki gbogbo awọn oṣiṣẹ fasiti naa maa reti lati gba owo oṣu tuntun tijọba apapọ buwọlu, bẹrẹ lati oṣu Kejila ti a wa yii.
Ọjọgbọn Ambali sọ pe sisan owo naa yoo mu iwuri ba awọn oṣiṣẹ lati le tẹpa mọ iṣẹ wọn ju ti tẹlẹ lọ, ati le le farajin fun afojusun fasiti ọhun.
Alaga naa lo sọrọ yii lasiko to n gba awọn ọmọ ẹgbẹ fasiti, Academic Staff Union of Universities (ASUU), ẹka ti ẹkun Ibadan lalejo ni gbọngan igbimọ (Council Chamber) ti ile-ẹkọ idokoowo to wa niluu Ilọrin lọsẹ to kọja.
Alaga igbimọ ASUU ọhun wa rọ awọn alakoso fasiti yii lati mu ọrọ igbayegbadun awọ oṣiṣẹ lọkunkundun, ki wọn si pese agbegbe ti yoo mu iṣẹ rọrun fun wọn, lati le fun wọn ni koriya, ki wọ le maa sa gbogbo ipa wọn fun idagbasoke.
Ọjọgbọn Ambali fi kun ọrọ rẹ pe lotitọ ni ọrọ igbayegbadun oṣiṣẹ jẹ wọn logun ni Kwara, to fi mọ afikun owo oṣu ati awọn ajẹmọnu loriṣiriṣi ni wọ ṣagbekalẹ rẹ.
Bakan naa lo sọ pe awọn alakoso fasiti ọhun ti bẹrẹ idunadura pẹlu ijọba lati dide sọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni fasiti wọn lori owo ajẹmọnu ti wọn pe ni Earned Academic Allowance (EAA).
No comments:
Post a Comment