Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ ati igbesẹ lati gbogun ti aisan ikọ ife ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Tuberculosis’.
Ambasidọ Olufolake AbdulRazaq to jẹ iyawo gomina ipinlẹ naa lo ṣiṣọ loju eto ifilọlẹ naa niluu Ilọrin l’Ọjọbọ, ọsẹ yii niluu Ilọrin.
Nibẹ ni Arabinrin AbdulRazaq ti ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ ti wọn pe ni Local Government Tuberculosis Champions (LGTC), ti yoo ṣagbatẹru gbogbo eto ọhun.
Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara ni wọn ti fi eto naa lelẹ, pẹlu bọọsi Hilux meji ati Kẹkẹ Maruwa mejilelọgbọn lati fi mu iṣẹ rọrun.
Nibẹ ni Arabinrin AbdulRazaq ti pe gbogbo iyawo awọn alaga kansu ni Kwara lati dide lewaju eto ọhun fun eto ilera awọn olugbe ipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment