Ijọba Eko ti afara Marine to wa ni Apapa pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 2, 2024

Ijọba Eko ti afara Marine to wa ni Apapa pa


Ijọba ipinlẹ Eko labẹ iṣakoso Babajide Sanwo-Olu ti kede wi pe ohun yoo ti afara Marine to wa ni Apapa pa, pẹlu erongba lati ṣiṣẹ atunṣẹ loju ọna naa.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2024 si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun 2025 ni ijọba yoo fi ti opopona ọhun pa.

Kọmiṣanna to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaṣeun Ọṣiyẹmi lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku to kọja, to si rọ awọn awakọ lati wa ọna miran ti wọn yoo maa gba laarin asiko naa.

Ọṣiyẹmi sọ pe ki awọn awakọ ti wọn n lọ lati Apapa lọ si opopona Lagos Island, ki wọn lọ maa gba layipo Costain lati gun afara Eko, iyẹn Eko Brigde, nibi ti wọn yoo gba lọ si Lagos Island.

Bakan naa lo sọ pe awọn ọna abuda lo wa fun awọn awakọ lati gba lọ si ibi ti wọn n lọ laarin asiko ti atunṣe ọhun yoo fi waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI