Ẹsẹ ko gbero ninu olu-iya ijọ alaṣọ funfun nni, Kerubu ati Serafu, iyẹn Cherubim and Seraphim Society to wa lagbegbe Okesuna ni Lagos Island, ipinlẹ Ekoo laipẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe n mura silẹ fun ayẹyẹ ọgọrun ọdun ti wọn da ijọ naa silẹ.
Lara ilana eto ayẹyẹ naa ni wọn ti sẹ iranti ipapoda oludasilẹ ijọ naa, Oloogbe St Capt Christiana Abiodun Emanuel to jade laye lọgbọn ọdun sẹyin.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni ayẹyẹ iranti ọgbọn ọdun naa waye ninu ijọ wọn.
Ọdun 2025 ni ijọ ọhun yoo pe ọgọrun-un ọdun ti wọn da a silẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Oriṣiriṣi alakalẹ eto lawọn igbimọ ayẹyẹ naa ti ṣe, eyi ti yoo mu ọjọ naa larinrin, lara eyi ti wọn ti fiwe pe awọn agba Wolii fun iṣẹ iranṣẹ.
Ọkan lara awọn ijọ to ya kuro labẹ Eternal Sacred Order of Cherubim and Seraphim to jẹ ti Moses Orimolade Tunolase ni ijọ ọhun.
Nibi ayẹyẹ iranti naa ni alakoso agba kaakiri agbaye, His Grace Babatunde Adebona ti sọrọ nipa oludasilẹ wọn, lori ipilẹ rere to fi silẹ ko to jade laye.
Adebona jẹ ko di mimọ pe ipa ribiribi ti oludasilẹ naa ko, lo jẹ ki wọn le maa tẹsiwaju titi di asiko yii.
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ ojo lo rọ, ti iji nla si fẹ, ṣugbọn to jẹ ko di mimọ pe nipa aanu Ọlọrun nikan ni wọn ko fi ṣubu.
"Nigba ti oludasilẹ wa jade laye, niṣe la lero wi pe gbogbo rẹ ti tan niyẹn, a bẹrẹ sii wo ibi ti a fẹẹ gbee gba, ṣugbọn Ọlọrun sọ pe ijọ ohun ni.
"Nipa igbagbọ la fi n ṣe ohun gbogbo, ti a si dupẹ pe Ọlọrun mu ileri rẹ ṣẹ fun wa. A ko lero wi pe a maa de ibi ti a wa lonii, ṣugbọn Ọlọrun jẹri ara rẹ.
"Ijọ yii ti gbooro kọja ohun ti a lero, kii ṣe mimọ-ọn ṣe wa bi ko ṣe pe oore ọfẹ Ọlọrun lo gbe wa ro. A ti ni ẹka kaakiri Naijiria ati agbaye lapapọ, ti wọn si n ṣe daadaa.
"Ẹ jẹ ka di opo Ọlọrun mu, bi a ba ni igbẹkẹle ninu Oluwa, a ko le ṣubu, ko si si ogun naa ti yoo bori wa."
Bakanna ni ọkan lara awọn alagba ijọ ọhun, Snr Apostle Kunle Adesona ninu ọrọ tirẹ sọ pe bi kii ba a ṣe ori otitọ ati ipilẹ ti awọn duro le, o ṣee ṣe ki ijọ ọhun ti tuka.
Adebona jẹ ko di mimọ pe nipa oore ọfẹ Ọlọrun ati atilẹyin awọn ọmọ ijọ, ni wọn fi duro ṣinṣin titi di asiko yii.
Ni bayii, ijọ naa ti ni ẹka ni orile-ede to pọ ti wọn si n gbooro si.
No comments:
Post a Comment