Akọnimọ-ọn-gba ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray, Okan Buruk, ti sọ pe agbabọọlu kan ṣoṣo ti awọn ko le fi ṣere lasiko yii ni Victor Osimhen, nitori pe pataki nla lo jẹ fun wọn.
Buruk lo sọrọ naa laipẹ yii fun iroyin Skorer.
Osimhen ti fi gbongbo rẹ lelẹ gidi fun ẹgbẹ agbabọọlu naa latigba to ti kuro ni Napoli.
Goolu mẹsan ni Osimhen ti gba ṣawọn, to si tun ti ṣe iranlọwọ goolu marun-un ninu ifarahan mẹsan to ti ni fun Galatasaray.
Buruk nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ọwọ aago ọmọ orileede Naijiria ko ṣee fa sẹyin lasiko yii, nitori pe o ti ṣe iranlọwọ to pọ fun wọn latigba to ti de.
“Osimhen ti ṣiṣẹ takuntakun, o ti gba goolu sawọn, bẹẹ lo tun ti ṣe iranlọwọ goolu. O kun oju oṣuwọn daadaa, o si n ṣe daadaa. O ti ṣe iranlọwọ goolu to ṣe pataki nilẹ Turkey ati Yuroopu,” Buruk sọ eyi fun Skorer.
“Lara awọn koko pataki rẹ ni pe o ti gba bọọllu fun ẹgbẹ agbabọọlu yii, ju goolu ati iranlọwọ goolu lọ. O si n gbiyanju gidi fun wa.”
No comments:
Post a Comment