Ijọba ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ ti ko din ni ida marundinlọgọrun (95.5%) ni wọn ti gba ẹkunrẹrẹ owo oṣu wọn fun oṣu Kọkanla to kọja.
Yatọ si owo oṣu, wọn tun ti gba awọn owo ajẹmọnu ati alekun (bonus) lori owo oṣu wọn.
Kọmiṣanna feto iṣuna nipinlẹ naa, Ọmọwe Hauwa Nuru lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita l’ọjọ Iṣẹgun to kọja, to si ni ida mẹrinlenimarun-un (4.5%) to ku ninu awọn ti ko tii gba owo oṣu wọn, ni wọn ti pada gba a.
O sọ pe awọn oṣiṣẹ naa ni wọn ko tii yanju eto ifọrukọsilẹ nipa gbigba nọmba idanimọ iṣẹ wọn ni wọn ti pada yanju rẹ, ti wọn si ti gba owo wọn lẹkunrẹrẹ.
Ọmọwe Nuru ṣalaye pe lati inu oṣu Keje, ọdun yii ni ijọba ti n kọrin sawọn oṣiṣẹ ijọba leti, lati lọ fi orukọsilẹ fun nọmba idanimọ iṣẹ ijọba, iyẹn KWSRRA.
Bakan naa lo tun ṣalaye siwaju pe ida mẹtadinlọgọrun ni awọn olukọ SUBEB n i wọn ti gba owo oṣu wọn, nigba ti awọn ida mẹta yooku ṣi ni iṣoro lati forukọsilẹ.
Bẹẹ lo tun fi kun un pe ida mẹtadinlọgọrin awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni wọn ti gba owo oṣu wọn ni kikun, nigba ti awọn ida mẹtalelogun yooku ko tii pari eto iforukọsilẹ fun KWSRRA.
No comments:
Post a Comment