Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun loun ti ṣetan lati gbe agba eto iṣuna ọdun 2025 fun ipinlẹ naa lọ siwaju ile igbimọ aṣofin lati buwọ lu.
Ọjọru ọsẹ yii, tii ṣe ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni Gomina sọ pe oun yoo gbe iwe aba naa lọ siwaju awọn aṣofin.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja lo yẹ ki Gomina Abiọdun gbe iwe aba naa lọ sile igbimọ aṣofin, ṣugbọn ti ijọba sọ pe eto naa ko nii waye mọ.
Ninu atẹjade ti Ṣakiru Adebakin to jẹ alakoso eto ile igbimọ aṣofin fi sita lonii, ọjọ Iṣẹgun, o ni gbogbo eto lo ti pari.
Adebakin sọ pe aba eto iṣuna ọhun ni yoo jẹ igbakeji ti Gomina Dapọ Abiọdun yoo maa gbe lọ siwaju awọn aṣofin latigba to ti pada sipo naa lẹẹkeji.
Bakan naa lo sọ pe eto onibeji ni eto naa yoo jẹ, pẹlu bi gomina yoo ṣe maa ṣe ifilọlẹ ile igbimọ aṣofin tuntun ti wọn ṣe atinṣe rẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe agogo mẹwaa owurọ ni eto ọhun yoo bẹrẹ, sibẹ o ni gbogbo awọn alejo ati akopa, to fi mọ awọn alakoso ninu iṣejọba ti gbọdọ wa ni ijokoo lati agogo mẹsan aabọ owurọ.
No comments:
Post a Comment