Gomina Adeleke dide iranlọwọ fun Ṣẹgun ti wọn dajọ iku fun lori adiẹ to jigbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 18, 2024

Gomina Adeleke dide iranlọwọ fun Ṣẹgun ti wọn dajọ iku fun lori adiẹ to jigbe


Gomina Ademola Adeleke tipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori gnedekunrin kan, Segun Olowookere ti ile ẹjọ ni ki wọn lọ yẹgi fun.

Ẹsun wi pe Olowookere ji adiẹ gbe ni wọn fi kan an, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.

Ninu atẹjade ti Gomina Adeleke gbe jade lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, o ni ki adajọ agba ipinlẹ naa tete dide iwadii.

Gomina Adeleke ni bi adajọ ba ṣewadii naa tan, ko rii daju pe orukọ ọmọkunrin naa wa ninu orukọ awọn ti wọn yoo fi oju aanu wo ki ọdun too pari.

Ninu atẹjade naa, “Mo ti ka nipa ẹjọ naa. Mo si da lilo ipo agbara ninu iṣejọba awa-ara-wa.

“Ninu ẹjọ yii, mo ti fun Kọmiṣanna feto idajọ lati bẹrẹ igbesẹ lati foju aanu wo ọmọkunrin naa.

“Ipinlẹ Ọṣun jẹ ipinlẹ ti kii ṣe ojusaaju ninu ofin. A ni lati rii daju pe a n daabo bo awọn eeyan nipa ilana.

“Mo ni lati sọ fawọn araalu wi pe ẹjọ naa n kọ mi lominu. Ti a si gbọdọ gbe igbesẹ pajawiri lati rii pe a ṣe ojuṣe wa gẹgẹ bi ijọba araalu.”

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ajọ World Institute of Peace dide lati jirẹbẹ fun ọmọkunrin naa.

Alakoso ajọ naa, ṣalaye pe ọdun mẹwaa ṣeyin ni wọn dajọ iku fun Olowookere nigba to wa lọmọ ọdun mẹtadinlogun lori ẹsun wi pe o ji adiẹ gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI