Gomina Abiọdun kẹdun iku Mahe, olori awọn oṣiṣẹ gomina ni Kwara to ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 29, 2024

Gomina Abiọdun kẹdun iku Mahe, olori awọn oṣiṣẹ gomina ni Kwara to ku


Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun, ti fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ si gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lori ipapoda olori awọn oṣiṣẹ rẹ,  Ọmọọba Mahe AbdulKadir.

Arọ ọjọ Abamẹta to kọja yii ni iroyin naa jade sita pe AdulKadir ku si ile iwosan awọn olukọni to wa niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara. 

Ninu atẹjade ibanikẹdun naa ti Abiodun kọ ranṣẹ ni Abamẹta yii, gomina ṣe apejuwe iku AbdulKadir gẹgẹ bi ọgbẹ ọkan nla ti ko ni ya jina. 

O ni gbogbo ẹbi ara, ọrẹ ati ojulumọ ni oun ki ku atẹmora nitori iku oloogbe naa gba omi loju ẹni. 

O sọrọ nipa ifaraṣíṣẹ oloogbe naa nigba aye rẹ, "AbdulKadir jẹ ẹni to ja fafa, to si fi ara jin si iṣẹ atisin ipinlẹ Kwara ati orile-ede Naijiria lapapọ." 

Siwaju si, Ọmọọba Abiọdun ni AbdulKadir jẹ oniwa-pẹlẹ ati ẹlẹmi irẹlẹ ti ki i si fi iṣẹ ṣere. 

O gba a ladura ki Ọlọrun fi ọrun kẹ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI