Gomina AbdulRazaq gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 wọle igbimọ aṣofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 20, 2024

Gomina AbdulRazaq gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 wọle igbimọ aṣofin


...iṣẹ ode, ile gbigbe, aabo ilu, eto ẹkọ lewaju

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti gbe iwe aba eto iṣuna ọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ lati ṣagbeyẹwo rẹ ko to di pe wọn buwọ lu.

Lonii, ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni Gomina AbdulRazaq gbe iwe aba naa lọ sile igbimọ aṣofin to wa niluu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ naa.

Nibi eto naa ni gomina tun ti kede wi pe oun yoo kọ ọtalenigba ile gbigbe tuntun fawọn araalu, ati pe akanṣe iṣẹ opopona yoo bẹrẹ adugbo, to fi mọ ilu Offa ati papa iṣere Lafiagi.

Ogojilelẹẹdẹgbẹta biliọnu (N540, 368, 119, 765.00) naira ni apapọ eto iṣuna naa, nigba ti awọn adawọle iṣẹ tuntun yoo gba ida mejilelogoji (62.1%), ti awọn iṣẹ to n lọ lọwọ yoo gba ida mejidinlogoji (37.9%).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI