Gẹdekunrin mẹrin to fipa ba ọmọdebinrin meji laṣepọ dero atimọle l’Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 6, 2024

Gẹdekunrin mẹrin to fipa ba ọmọdebinrin meji laṣepọ dero atimọle l’Ọṣun


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ni ọrọ awọn gendekunrin mẹrin ti wọn jọ digun fipa ba awọn ọmọdebinrin ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtala lọ laṣepọ ṣi n jẹ kayeefi.

Ileeṣẹ aabo oju-lalakan-fi-nṣọri, iyẹn Sifu Difẹnsi sọ pe ilu Iwo to wa nijọba ibilẹ Iwo, ipinlẹ Ọṣun lọwọ ti tẹ awọn mẹrẹẹrin naa.

Sadiq Ọpẹyẹmi, ẹni ọgbọn ọdun; Afeez Ọlalekan, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn; Ismail Ibrahim, ọmọ ọgbọn ọdun ati Abdulahi Garba toun jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ni ọwọ tẹ.

Ọga agba ileeṣẹ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Igbalawọle Ṣotiyọ, lasiko to n foju awọn mẹrin naa han fawọn akọroyin niluu Oṣogbo l’Ọjọbọ to kọja yii, o ni ọmọdebinrin meji ni awọn mẹrẹẹrin fipa ja ibale wọn.

Ṣotiyọ ṣalaye pe ẹẹdẹgbẹta naira ni awọn mẹrẹẹrin ọhun fi tan awọn ọmọdebinrin ọhun, ati pe ọpọ igba ni wọn ti ba awọn ọmọ naa laṣepọ.

Ọga agba naa sọ pe awọn mẹrẹẹrin lo pada jẹwọ pe lotitọ ni ẹsun ti wọn fi kan awọn, ati pe iṣẹ eṣu ni.

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ naa n gbe pẹlu awọn aya ati baba agba wọn ni, ati pe ọna lati maa wa ounjẹ funra wọn lo jẹ ki wọn ṣagbako awọn ọkunrin naa.

O ni awọn to n tọju awọn ọmọ naa ko ri itọju to pe ye, ti wọn si n wa ọna abayọ lati tọju ara wọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn mẹrẹẹrin yoo foju ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to tọ si wọn, sibẹ o rọ awọn araalu lati maa ṣabojuto awọn ọmọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI