Eto ipatẹ ọja ita gbangba bẹrẹ ni Kwara lọsẹ yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 4, 2024

Eto ipatẹ ọja ita gbangba bẹrẹ ni Kwara lọsẹ yii


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe eto ipatẹ ọja ita gbangba ọlọdọọdun ti wọn n pe ni ‘Trade Fair’ nni, ẹlẹẹkọkanla iru rẹ yoo bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjila, ọdun 2024 ni ijọba Kwara sọ pe eto naa yoo bẹrẹ lakọtun, pẹlu awọn alakalẹ eto ọlọkan-o-jọkan.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto okoowo ati idagbasoke imọ-ẹrọ tẹkinọlọji nipinlẹ naa, Damilọla Yusuf Adelọdun sọ pe papa iṣere tiluu Ilọrin ni ipatẹ ọja ita gbangba naa yoo ti waye.

O ni oniruuru awọn olokoowo kaakiri Naijiria ni wọn ti fi erongba wọn han lati darapọ mọ ipatẹ ọja ita gbangba tọdun yii.

Adelọdun sọ pe ọna ara-ọtọ ni eto tọdun yii yoo gba waye, nitori pe awọn olokoowo ati oniṣẹ ọwọ yoo pọ jaburata lati kopa.

Bakan naa lo sọ pe awọn akọṣẹmọṣẹ nipa imọ ẹrọ yoo wa nibẹ fun idanilẹkọọ loriṣiriṣi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI