Ẹgbẹ pasitọ oloṣelu ni CAN ati PFN, aṣoju ifẹ ijọba ni wọn – Wolii Ayodele tun ju bọmbu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 20, 2024

Ẹgbẹ pasitọ oloṣelu ni CAN ati PFN, aṣoju ifẹ ijọba ni wọn – Wolii Ayodele tun ju bọmbu


Wolii Elijah Babatunde Ayodele, alaṣe ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritua Church to wa niluu Eko ti sọ pe ko si nnkan toun fẹẹ fi ẹgbẹ onigbagbọ Naijiria, iyẹn CAN ṣe, nitori pe wọn ti yẹ kuro ninu ilana idasilẹ.

Gbajugbaja agba Wolii naa lo sọrọ yii nibi eto asọtẹlẹ ọlọdọọdun to maa n waye ninu ijọ INRI to wa l’Ekoo, ti wọn ṣe lonii, ọjọ Ẹti.

Wolii Ayodele nigba to n dahun ibeere, o ni ko si nnkan toun fẹẹ sọ nipa awọn ẹgbẹ naa.

“Ko sohun ti mo fẹẹ sọ nipa ẹgbẹ CAN ati PFN, ẹgbẹ awọn pasitọ oloṣelu ni wọn jẹ. Wọn n ṣoju ifẹ ijọba ni, kii ṣe ohun ti awọn Kristiẹni n fẹ. Ko si ododo kan nini CAN ati PFN.

“Wọn kan wa nibẹ nitori apo ara wọn, ohun ti wọn n fẹ, ati ifẹ ọkan ara wọn ni. Wọn ko ṣee ran lọwọ nitori pe wọn ko ni igboya ninu ara wọn.

“Awọn ọga wọn ti ja wọn gba. CAN ati PFN ko ba ilana Bibeli mu, wọn kan n ṣe fun igbadun aye lasan ni. Ẹgbẹ oṣelu Kristẹẹni ni wọn, wọn si wa n pe ara wọn ni ‘Penticostal’, ko si nnkan to n jẹ bẹẹ, ifẹ ara wọn ni wọn wa fun.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI