Ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria ti fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Oyo lati kẹdun iṣẹ ijamba itẹra-ẹni-pa to waye niluu Ibadan, eyi to mu ẹmi awọn ọmọde ti ko din ni marundinlogoji lọ.
Wọn lo pọn dandan fawọn lati ba igbekeji alaga ẹgbẹ naa, Seyi Makinde ati gbogbo awọn mọlẹbi to padanu awọn ọmọ wọn, to fi mọ awọn to fara kaaṣa.
Atẹjade ọhun ti gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq to jẹ alaga wọn buwọ lu, lo ti sọ pe awọn yoo darapọ mọ Aarẹ lati pe fun iṣẹ iwadii ohun to ṣokunfa ijamba naa.
“A darapọ mọ ibanujẹ apapọ, ati pe ọkan wa, wa pẹlu gbogbo awọn ti ọrọ kan – paapaa julọ bi eto ayẹyẹ ọdun yii ṣe bẹrẹ! A darapọ mọ Aarẹ lati pe fun iwadii lati dẹkun irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ to ṣee ṣe ko waye lọjọ iwaju leyikeyi ẹka orileede yii.”
No comments:
Post a Comment