Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Committee of Unions in Tertiary Institutions (CUTI) nipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa lori bo ṣe tete n san owo oṣu ajẹmọnu (allowances) wọn lai fi akoko ṣofo.
Ọrọ ọhun lo jade lasiko ti awọn alakoso ẹgbẹ naa ṣabẹwo si Kọmiṣanna feto ẹkọ giga, Ọmọwe Mary Ronke Arinde laipẹ yii ni ọfiisi rẹ to wa niluu Ilọrin.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Falade Gbenga fi sita, CUTI sọ pe ohun iwuri lo n jẹ fun wọn lati maa tete gba owo oṣu ajẹmọnu wọn lasiko, eyi ti wọn lo ti pẹ tawọn ri iru rẹ gbẹyin.
Alaga ẹgbẹ naa, Kọmureedi Musa Mustapha sọ pe awọn yoo tubọ maa ṣagbatẹru ijọba labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq si rere, nitori pe ẹlẹyin aanu ni.
Ṣaaju asiko yii, Ọmọwe Arinde sọ pe ọrọ igbayegbadun araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba jẹ gomina logun pupọ, idi ree to si ni AbdulRazaq fi n ṣe iranwọ to yẹ lasiko.
No comments:
Post a Comment