Ẹgbẹ awọn aṣewo lorileede Naijiria labẹ aburada ẹgbẹ Nigeria Sex Workers Association (NSWA) ti rawọ ẹbẹ sawọn alakoso ileeṣẹ agbofinro lorileede naa lati maa ṣe awọn oṣiṣẹ wọn jẹjẹ.
Wọn ni iya ti awọn agbofinro fi n jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti pọ ju, ati pe ko bojumu to.
NSWA sọrọ naa laipẹ yii ninu atẹjade ti wọn fi sita, eyi to tẹ ileeṣẹ iroyin NAN lọwọ lonii, ọjọ Iṣẹgun.
Atẹjade ọhun alakoso agba wọn, Amaka Enemo buwọ lu ni wọn ti sọ pe ọna ti awọn agbofinro n gba lati fiya awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lọna aitọ n kọ wọn lominu.
O ni bi wọn ṣe n fiya bii lilu jẹ wọn, naa ni wọn tun n lọ wọn lọwọ gba kaakiri Naijiria.
Enemo jẹ ko di mimọ pe igbayegbadun awọn eeyan wọn lo jẹ wọn logun, ti awọn si gbọdọ dide lodi si oniruuru iya aitọ to ba fẹẹ jẹ wọn.
No comments:
Post a Comment