Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ogbontarigi oni waasi agbaye nni, Sheik Muhydeen Ajani Bello ti jade laye, to si jẹ pe latigba ti iroyin ọhun ti bọ sinu afẹfẹ l'awọn eeyan ti n kẹdun iku rẹ.
Aarọ oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun ni Sheik Ajani Bello ki aye pe o digboṣe lẹyin aisan rampẹ to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo.
Lara awọn to fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi agba aafa naa ni Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko.
Sanwo-Olu ni gbogbo aye yoo maa ṣe iranti Sheik Ajani Bello fun akitiyan rẹ nipa gbigbe ẹsin Islam larugẹ.
"Lorukọ mọlẹbi mi, awọn eeyan ati ijọba ipinlẹ Eko, mo ki awọn mọlẹbi, ọrẹ, ati gbogbo awọn eeyan lagboole Musulumi ku ara fẹra ku yi alẹnulọrọ ẹsin Islam, Sheik Muyideen Ajani Bello, ẹni to jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin.
"Oloogbe Sheikh Alaaji Muyideen Ajani Bello ni wọn yoo maa ṣeranti rẹ fun ti akitiyan ati ifarajin fun ipolongo Islam," Sanwo-Olu sọrọ.
No comments:
Post a Comment