Ẹ wa gbọ ogun ti Kunle Afolayan sọ nipa Gbenga Adeboye ati Tunde Kelani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 26, 2024

Ẹ wa gbọ ogun ti Kunle Afolayan sọ nipa Gbenga Adeboye ati Tunde Kelani


Ogbontarigi oludari ere tiata nni, Kunle Afolayan ti gbe oṣuba kare fun awọn agba amuludun nni, Oloogbe Gbenga Adeboye ati Tunde Kelani lori ipa ti wọn ko nigbesi aye rẹ.

Afolayan ninu ọrọ ati awọn aworan to gbe soju opo ayelujara rẹ laipẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn meji naa ko ipa ribiribi nigbesi aye oun.

O ṣalaye pe awọn meji naa lo gbe oun de ibi toun de lonii, to si loun ko le gbagbe wọn.

O ni ipa to jọju ni wọn ko ninu irin ajo sidi iṣẹ tiata to yan laayo.

Ninu ọrọ rẹ, o ni
"Mo dupẹ lọpọlọpọ lọwọ awọn awokọṣe ti wọn ko ipa ribiribi nigbesi aye mi. Buọda Gbenga Adeboye ti a jọ pin ọjọ ibi, ti wọn si tun ko ipa to jọju laye mi lọna to pọ. Tunde Kelani lo tọ mi sọna si ipa rere."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI