Bukọla Saraki, Abdulfatah Ahmed yoo foju bale ẹjọ lori idigunjale banki Ọffa to waye lọjọsi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 14, 2024

Bukọla Saraki, Abdulfatah Ahmed yoo foju bale ẹjọ lori idigunjale banki Ọffa to waye lọjọsi


Onidajọ T.O Osuolale-Ajayi ti sọ pe awọn gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹri, Bukola Saraki ati Abdulfatah Ahmed, to fi mọ adajọ agba nipinlẹ naa yoo yọju lati sile ẹjọ giga lati sọ tẹnu wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn lori idigunjale to waye lawọn banki ilu Ọffa lọdun mẹfa sẹyin.

Ọjọ kẹtala, oṣu kinni, ọdun 2025 ni Onidajọ T.O Osuolale-Ajayi sọ pe awọn eeyan naa yoo yọju lati sọ tẹnu wọn niwaju ile ẹjọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ karun-un, oṣu kẹrin, ọdun 2018 ni awọn adigunjale ya wọ awọn banki niluu Offa, nibi ti awọn ti ko din ni mẹtalelọgbọn ti dero ọrun alakeji.

Laipẹ yii ni ile ẹjọ giga tipinlẹ Kwara da ẹwọn gbere fawọn adigunjale marun-un tọwọ tẹ, lẹyin ti wọn ti jẹwọ pe lotitọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Lẹyin idajọ naa ni awọn mọlẹbi awọn to ba iku ojiji pade nibi idigunjale naa dide lati pe ẹjọ miran, ti wọn si n rọ ile ẹjọ lati jẹ ki Sẹnetọ Bukọla Saraki ati Abdulfatah Ahmed ti wọn ti figba kan ri jẹ gomina wa sọy tẹnu wọn.

Awọn mọlẹbi naa sọ pe niwọn igba ti awọn adigunjale naa ti jẹwọ pe awọn mejeeji yii lo ran wọn niṣẹ lati lọ digunjale, ati pe awọn ni wọn ko ibọn ati awọn nnkan ija oloro, to fi mọ awọn mọto ti wọn gbe lọ ṣiṣẹ naa fun wọn, o di dandan ki wọn foju ba ile-ẹjọ.

Agbẹjọro awọn bii Ọgbeni Abraham Olufemi Makinde, Ọgbeni Lateef Taiye Raheem, Ọgbeni Adeshina Pelemo Adesanmi ati Arabinrin Monsurat Aramide Adebayo lo pe ẹjọ naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Awọn ti wọn pe lẹjọ ni Gomina ipinlẹ Kwara, adajọ agba nipinlẹ Kwara, Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Bukọla Saraki ati Abdulfatah Ahmed toun naa jẹ gomina ana ni Kwara.

Ile ẹjọ ti wa paṣẹ pe ki wọn lọ fun gbogbo awọn tọrọ naa kan niwe lati yọju sile ẹjọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI