Ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorileede Naijiria, Nation Drugs and Law Enforcement Agency, NDLEA ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan Egwu Phillip Inya, lori ẹsun gbigbe egboogi oloro.
NDLEA sọ pe Egwu ko niṣẹ meji to kọja gbigbe egboogi oloro, ṣugbọn ti wọn ni iṣẹ abanikọle lo fi n boju kaakiri.
Asiko ti wọn lo fẹ lọ gba awọn ọja kan ti wọn ko wọle lati orileede South Africa lọwọ palaba rẹ segi.
Ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun yii ni wọn sọ pe ọwọ tẹ Egwu ni ibudokọ Okeyson
Motor Park to wa nipinlẹ Ẹnugu.
Wọn ni bo ṣe debẹ lati gba awọn ọja ti wọn pe ni 'pressure machines' naa, ni ọwọ ajọ NDLEA tẹ ẹ.
Inu awọn ọja naa la gbọ pe wọn tọju awọn egboogi 'Loud' naa ti iwọn rẹ jẹ '7.40kgs' si, ki aṣiri ma ba a tu sita.
Agbẹnusọ ajọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi, lasiko to n ṣalaye fawọn akọroyin jẹ ko di mimọ pe papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport
(MMIA), to wa ni Ikẹja, l'Ekoo ni ọja ọhun gba wọn Naijiria lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2024.
Babafẹmi ni iṣẹ ofintoto ti awọn ṣe lo jẹ ki aṣiri tu si wọn lọwọ, to si lawọn tete tọpinpin Egwu de ibi to ti lọ gba a.
No comments:
Post a Comment