Baale ile to lu iyawo rẹ pa dero kọọtu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 19, 2024

Baale ile to lu iyawo rẹ pa dero kọọtu


‘Iṣẹ esu ni, e foju aanu wo mi’, lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n jade lẹnu baale ile ẹni ọdun marunlelaadọta kan, Eseni Chima, nigba to foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun ipaniyan.

Chima ni wọn lo lu iyawo rẹ, Ugochukwu pa laipẹ yii niluu Abakaliki, ipinlẹ Ebonyi.

Ọjọ Iṣẹgun, Tuside to kọja yii ni wọn foju Chima ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Abakaliki.

Agbefọba to tako ọkunrin naa niwaju ile-ẹjọ, Emmanuel Monday sọ pe ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan, ọdun 2024 ti a wa yii ni Chima lu iyawo rẹ pa lojuje ọgọta, opopona Ogbaga, Kpirikpiri, ijọba ibilẹ Abakaliki.

Monday sọ pe irin nla kan ni Chima fi lu iyawo rẹ titi to fi dakẹ lọjọ naa.

O ni ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Ebonyi ni abala 319 (1) lọdun 2009.

Bo tilẹ jẹ pe Chima bẹbẹ niwaju adajọ, ṣugbọn Onidajọ Chinedu Agama sọ pe oun ko le gbọ ẹbẹ rẹ, ati pe ko lẹsẹ nilẹ.

Onidajọ naa wa paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa gbe iwe ẹsun naa lọ siwaju awọn alakoso ileeṣẹ Director of Public Prosecution fun amọran.

Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2024.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI