Alaga ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, Ọla Olukayọde ti sọ pe ọna abayọ kan ṣoṣo lati gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu ni ki awọn ọdọ fọwọsowọpọ.
Olukayọde sọ pe ohun to ṣe pataki ni fun awọn ọdọ lati fimọ ṣọkan lati gbogun ti awọn ikooko ninu iwa ajẹbanu, ki iwa naa le dohun igbagbe patapata.
Siwaju sii ni ọga agba naa jẹ ko di mimọ pe bi araalu ko ba tete gbogun ti iwa naa lasiko to yẹ, yoo tubọ maa ṣe ipalara fun awọn iran to n bọ lẹyin, paapaa awọn ọdọ asiko yii.
Olukayọde lo sọrọ yii niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi eto ti wọn fi saami ọjọ gbigbogun ti iwa jibiti lagbaye, iyẹn 2024 World Anti-Corruption Day.
O ni gbogbo eeyan lo ni ojuṣe lati ṣe lati dẹkun iwa naa, paapaa laaarin awọn ọdọ ju eyikeyi ọjọ ori lọ.
“Ọkan lara awọn ipalara ti jibiti ori ayelujara n ṣe lo wa laarin awọn ọdọ. Ifẹ lati ni owo lo n jẹ gaba lọkan awọn ọdọ bayii.
“Eyi gan-an lo fa a ti awọn alakoso ile-ẹkọ giga ṣe lakaka lati jẹ ki awọn ọdọ yago fun jibiti ori ayelujara.
“Gbogbo ọdọ lo ni anfaani kan naa si erongba wọn. Ju gbogbo rẹ lọ, eyi ko ṣee ṣe ni agbegbe ti a n fi ọmọ kan kẹ ọkan, ti ojusaaju si wa.
“Eyi ko dara fun awọn ọdọ, ati pe idi pataki ree to fi pọn dandan fun awọn ọdọ lati fọwọsowọpọ ninu ija lati gbogun ti iwa jibiti.”
No comments:
Post a Comment