Awọn alakoso OSCOTECH fi oye 'Fellow' da Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes lọla l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 14, 2024

Awọn alakoso OSCOTECH fi oye 'Fellow' da Aarẹ EmmanuelKing, alaṣẹ Adron Homes lọla l'Ọṣun


Awọn alakoso ile eko giga kọlẹẹjì imọ ẹrọ nipinlẹ Ọṣun, Osun State College of Technology (OSCOTECH) ti fi aami ẹyẹ to ṣe pataki da alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ to n ta ilẹ ati dukia lorileede Naijiria, Aarẹ Adetola EmmanuelKing lọla.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ami ẹyẹ idalọla naa ni wọn oe ni ọmọ ẹgbẹ oataki, iyẹn Fellow ni wọn fi da Aare Adetola Emmanuelking ọhun lọla.

Wọn ni alaṣẹ Adron Homes yẹ lẹni ti wọn n bu ọla ati iyi fun, lori awọn idagbasoke to ti mu ba eto ọrọ ile gbigbe lorileede Naijiria.

Awọọdu Fellow OSCOTECH ni wọn gbe wọ ọmọ bibi ilu Iliṣan nipinlẹ Ogun naa.

Eto ọhun lo waye nibi ayẹyẹ ikẹkọọgboye ti ile ẹkọ naa, ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti wọn ṣe papọ ninu ọgba to wa niluu Esa-Oke, ipinlẹ Osun.

Lara awọn to wa nibẹ ni Gomina Ademola Adelek tipinlẹ Osun, awọn aṣofin ipinlẹ naa, awọn akọwe agba, to fi mọ Oba Adeyemi Akanbi ati Oba Festus Kayode Awogboro. 

Kii ṣe alaṣẹ Adron Homes nikan ni wọn fi oye yii da lọla, wọn tun fi da awọn bii Owaniran tiluu Esa-Oke, Oba Adeyemi Adediran, ati Yeyeluwa Modupeola Adeleke Sanni, aburo gomina ipinlẹ Osun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI