Agbẹnusọ Atiku Abubakar, oludije sipo aarẹ tẹlẹri lorileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ṣẹgun Ṣowunmi ti sọ pe ọga oun ko tii ba oun sọrọ boya yoo ṣi tun pada jade du ipo aarẹ lọdun 2027.
Ṣowunmi, ẹni toun naa ti figba kan ri jẹ oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lo sọrọ yii nibi ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels nipinlẹ Eko.
Agba alẹnulọrọ ninu PDP naa sọ pe gbogbo ibeere toun n beere lọwọ ọga oun, Abubakar lati mọ boya o ṣi ni erongba lati du ipo aarẹ lọjọ iwaju ni ko da oun lohun.
O ni ṣugbọn pẹlu boun ṣe n wo o, o ṣee ṣe ko jẹ pe Abubakar n ṣe igbaradi lati tun darapọ mọ idije naa fun igbakẹta lera wọn.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Atiku Abubakar jẹ ọkunrin kan ti mo fẹran pẹlu egungun mi. Ọkan maa tete jẹra, ṣugbọn egungun jẹ ohun kan ṣoṣo ti ko le jẹra.
“Mo ti beere lọwọ rẹ lẹẹmeji, wi pe ‘njẹ ẹ ṣi maa jade du ipo? Njẹ ẹ ti ṣetan? Bi ẹ ba ṣi fẹẹ jade du ipo, ki ni ka ṣe pẹlu ilana wa? Bi ẹ ko ba tii ṣetan, a ni lati ṣe nnkankan to yatọ’.
“A ko le maa ṣe ohun kan naa, ka si maa reti esi miran ni igba meji ọtọọtọ pẹlu awọn alafo.
“Mo jẹ ọkunrin to dara lati beere lọwọ rẹ fun igba kẹta. O dakẹ, o ṣi n ronu lori rẹ ni. Ko tii sọ pe ‘rara’, ko si tii sọ pe ‘bẹẹni’, ati pe mo bọwọ fun eyi.
“Gbogbo ọlọpọlọ eeyan gbọdọ mọ pe ẹru nla ni ọrọ eto idibo jẹ. Ko tii si ẹda eeyan naa to ṣi ni iru iriri, ipenija ati paapaa iru iwa ọdalẹ ti Atiku ti farada, ti ko nii tun ironu rẹ pa ko to di pe o sọ pe ‘Mo maa jade’.
“Nko kii ṣiṣẹ ti mo ma maa ronu le lori. Mo ti beere lọwọ rẹ lẹẹmeji ọtọọtọ, ko si fun mi ni esi. Nigba to ba pada fun mi lesi, ohunkohun ti esi naa ba jẹ, a maa fi gbe e lọ si ipele to kan ni.”
No comments:
Post a Comment