Ajọ NUC fontẹ lu ilana eto ẹkọ tuntun mẹwaa fun KWASU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 22, 2024

Ajọ NUC fontẹ lu ilana eto ẹkọ tuntun mẹwaa fun KWASU



Ajọ to n ṣakoso awọn ile ẹkọ giga lorileede Naijiria, National Universities Commission, NUC, ti buwọ lu ilana eto ẹkọ tuntun mẹwaa fun fasiti ipinlẹ Kwara fun eto ẹkọ ọdun 2024 si 2025.

Ontẹ naa to wa ninu iwe ti wọn fi ranṣẹ giwa agba, Ọgbọn Shaykh-Luqman Jimoh, eyi ti adele alakoso ajọ naa, Abubakar M. Girei buwọ lu, ni wọn ti fidi rẹ mulẹ.

O ni awọn buwọ lu awọn ilana eto ẹkọ tuntun lẹyin ayẹwo finnifinni ti wọn ṣe.

Awọn ilana eto ẹkọ naa ni:

1. B.Sc. Estate Management
2. B.Sc. Geography
3. B.Sc. Urban and Regional Planning
4. B.Eng. Mining Engineering
5. B.Sc. Marketing
6. B.Sc. Sociology
7. B.Sc. Criminology and Security Studies
8. B.Sc. Physiology
9. B.Sc. Human Anatomy
10. B.Sc. Cyber Security

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni ajọ NUC buwọ lu iwe aṣẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI