‘Ẹ ṣe mi jẹjẹ, ẹ ṣaanu mi’ lọrọ ẹbẹ to n jade lẹnu gendekunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Adekunle Obideyi tọwọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun tẹ nipinlẹ Ọṣun lori ẹsun wi pe o ji awọn ire oko bii Ọgẹdẹ ati Kokoo.
Adekunle, ọmọ bibi ilu Erinmọ-Ijẹṣa, ni wọn lo na papa bora lẹyin to ji awọn ire oko naa.
Nigba to n ṣalaye fawọn akọroyin niluu Oṣogbo lọjọ Aje, ọsẹ yii, alakoso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Isaac Ọmọyẹle sọ pe ofintoto ati iwadii kikun lọwọ fi tẹ Adekunle.
“Amọtẹkun sare bẹrẹ iṣẹ ofintoto lori iroyin ti a gba, ohun la fi tọpinpin lati mu Adekunle nibi to sapamọ si ni Erinmọ-Ijẹṣa,
“Nigba ti a fọrọ wa a lẹnu wo, afurasi naa jẹwọ iwa ọdaran rẹ, to si tun jẹ ko di mimọ pe kii ṣe igba akọkọ ree toun yoo maa jalẹ.”
Ọga Amọtẹkun naa wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti fa Adekunle le awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii.
No comments:
Post a Comment