Adanu nla n’iku Sheik Ajani Bello jẹ fun Naijiria - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 6, 2024

Adanu nla n’iku Sheik Ajani Bello jẹ fun Naijiria - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq ti ṣapejuwe iku agba oni waasi nni, Sheik Muhyideen Ajani Bello gẹgẹ bi adanu nla fun Naijiria.

AlbdulRazaq to jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Naijiria lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita lati fi kẹdun olori ẹlẹsin naa to jade laye lonii, ọjọ Ẹti.

Gomina ni ojiji ni iroyin iku naa ba oun, to si jẹ ibanujẹ ọkan.

Lasiko to n ṣapeju ipa ti oloogbe naa ko, Gomina AbdulRazaq ni ogbontarigi ni oloogbe naa jẹ, to si ti n lewaju lati bi ogoji ọdun sẹyin.

Ninu atẹjade ọhun ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye buwọ lu, AbdulRazaq ni gbogbo Naijiria ni yoo ṣafẹri oloogbe naa.

O ni o ṣeni laanu pe asiko ipenija ti Naijiria nilo rẹ julọ ni iku wọle mu lọ lai ro tẹlẹ.

“O duro ṣinṣin ninu otitọ ati olukora-ẹni nijanu kaakiri ẹka. O maa n sọ otitọ fun awọn to wa niṣakoso agbara pẹlu ọgbọn ati ọna to tọ,” AbdulRazaq sọ bẹẹ.

Bakan naa lo gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa si afẹfẹ rere.

Bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun duro ti awọn mọlẹbi to fi silẹ saye lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI