Orin ọpẹ lawọn ẹlẹwọn mẹrinla kan mu sẹnu lọsẹ to kọja yii nigba ti adajọ agba nipinlẹ Ogun, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu tọwọ bọwe itusilẹ wọn.
Onidajọ Dipẹolu ṣe eyi lasiko igbesẹ lati mu ẹdinku ba awọn to wa lọgba ẹwọn, iyẹn nileeṣẹ eto idajọ wa niluu Abẹokuta.
Adajọ agba naa ni orukọ awọn ẹlẹwọn to gba ominira naa, ati ontẹ, to fi mọ aworan wọn ni wọn ti ṣe akọsilẹ rẹ labẹ ofin lati ma ba a ni iṣoro lọjọ iwaju.
Bakan naa lo tun tọka si awọn iṣẹ ileeṣẹ eto idajọ lati maa gbe ododo larugẹ ati lati ma ṣe ṣe ojusaaju ninu agbekalẹ wọn.
Ẹlẹwọn mẹfa lati ọgba ẹwọn Ijẹbu-Ode, mẹta lati ọgba ẹwọn Ṣagamu, mẹrin lati ọgba ẹwọn Ọba ati ẹọkan ni ọgba ẹwọn Ibara ni wọn gba itusilẹ naa.
No comments:
Post a Comment