AbdulRazag sọ awọn anfaani ti awọn oludokoowo lagbaye le jẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 9, 2024

AbdulRazag sọ awọn anfaani ti awọn oludokoowo lagbaye le jẹ ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara lo ti tọka si oriṣiriṣi anfaani ti awọn oludokowo kaakiri agbaye le jẹ, bi wọn ba wọ ipinlẹ naa lati da iṣẹ silẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria naa sọ pe awọn agbekalẹ iṣakoso oun yoo ṣe anfaani pupọ fun awọn oludaṣẹ silẹ.

Gomina ṣalaye awọn ọrọ wọnyi nibi akanṣe eto 'Africa Investment Forum (AIF) Market Days' to waye niluu Rabat, orileede Morrocco, eyi ti African Development Bank Group gbe kalẹ.

AbdulRazaq ni awọn agbekalẹ bii 'Agroprocessing Zone' ati 'Ilorin Smart City' ni yoo ko ipa to pọ ninu okoowo awọn oludokowo nipinlẹ naa.

“Mo ni anfaani lati kopa nibi akanṣe eto Africa Investment Forum (AIF) Market Days.

“Lasiko eto naa, mo darapọ mọ itakun ati ijiroro pẹlu awọn alabaṣiṣẹpọ ti wọn jẹ ọjọgbọn fun awọn agbekalẹ wa ti yoo ṣe rere, bii 'agro-processing zone, ati Ilorin Smart City',” Gomina Abdulrazaq sọ ninu atẹjade to fi sawọn oju opo ayelujara.

Aworan loriṣiriṣi...







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI