Aarẹ Tinubu yoo gbe aba eto iṣuna tiriliọnu mejidinlaadọta naira fọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 12, 2024

Aarẹ Tinubu yoo gbe aba eto iṣuna tiriliọnu mejidinlaadọta naira fọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin


Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari lati gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin agba lati ṣagbeyẹwo rẹ, ko to di pe wọn buwọ lu.
 
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni Aarẹ Tinubu yoo gbe iwe aba eto iṣuna ọhun lọ siwaju awọn aṣofin agba.
 
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ọhun, Godswill Akpabio lo kede sita lasiko ijokoo wọn, to si ni aarẹ ti ranṣẹ si wọn.
 
“Aarẹ ti fi erongba rẹ ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba lati gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 wa sibi ipade ile igbimọ aṣofin ti yoo waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024,” o sọ bẹẹ.
 
Ṣaaju asiko yii ni minisita feto iṣuna ati agbekalẹ eto iṣuna, Atiku Bagudu ti kede pe tiriliọnu mejidinlaadọta din diẹ, N47.9 naira ni gbogbo aba eto iṣuna ọhun yoo jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI