Aarẹ Tinubu wọ ipinlẹ Eko fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 19, 2024

Aarẹ Tinubu wọ ipinlẹ Eko fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun


Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti wọ ilu Eko fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi to wọle de, ati ọdun tuntun to n bọ lọna.

Agogo mẹta kọja iṣẹju mẹtalelogun ọsan, Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni Aarẹ Tinubu balẹ si papakọ ofurufu Murtala Mohammed International Airport to wa ni Ikeja, ipinlẹ Eko.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ, Bayo Onanuga fi sita, o jẹ ko di mimọ pe ilu Eko ni Aarẹ Tinubu yoo ti ṣọdun Keresimesi.

Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko; igbakeji rẹ, Femi Hamzat; awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ati lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko ni wọn lọ pade Aarẹ bo ṣe balẹ si papa ofurufu.

Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni aarẹ gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin lati ṣagbeyẹwo rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI