Ẹsẹ ko gbero ni papa iṣere Gateway to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti to kọja nibi ayẹyẹ ọdun ọmọ ilẹ Remo, akọkọ iru rẹ to waye.
Gbogbo ọmọ bibi ilẹ Remo kaakiri agbaye ni wọn peju sibẹ lati fi idunnu wọn han gẹgẹ bi ọmọ ilu naa.
Bi a ṣe ni awọn gbajugbaja nidi oṣelu, bẹẹ naa la tun ri awọn ilu-mọ-ọn-ka nidi ere idaraya, amuludun, eto ọrọ ajẹ, to fi mọ eto ẹkọ ati bẹẹbẹẹlọ.
Awọn bi Gomina ana nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Gbenga Daniel; olori awọn oṣiṣẹ aarẹ Naijiria, Ọnarebu Femi Gbajabiamila; Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ati iyawo rẹ; Ewusi tiluu Makun, Ọba Timothy Oyesola Akinsanya;
ORUNAGBA II, Chairman of Adron Group and Otun Akile of Remoland Aare Adetola Emmanuelking, amongst others.
Gbogbo ilu to wa labẹ ilẹ Remo bii Epe, Makun, Iperu, Irolu, Emuren, Ogere, Ikenne, Ilara, Ode remo, Isara, Ipara, Ilishan, Soyindo, Ijagba, Ado, Ode lemo, Ibido, Idena, Ogijo, Atayo, Eposo, Idado, Latawa, Oko, Ipoji, Lowa ibu, Igbepa, Ijoku, Iraye, Ilupeju, Iraniken, Okeselu, Simawa, Ilaye, Iraye, Agura, Igode, Sotubo, Ariye , Araromi, Imushin, Imeji, Agbehinsa , ati awọn miran lo wa nibẹ.
Alakoso agba fun ileeṣẹ Adron Homes lo gba iyi to pọ pẹlu imura rẹ to gbe aṣa ati iṣe ilẹ Remo larugẹ.
No comments:
Post a Comment